Dapo Abiodun
Dapo Abiodun(tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkándínlọ́gbọ̀n oṣù Kàrún-ún ọdún 1960) jẹ́ oníṣòwò àti olóṣèlú ọmọ ilẹ̀ Yorùbá láti ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn nígbàtí O borí ìdìbò ti Gómìnà ni ọdún 2019 lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́-òṣèlú (APC).[1] Dàpọ̀ Abíọ́dún ni olórí ìgbìmọ̀ ti Corporate Affairs Commission.[2] Ó tún jẹ́ alakoso àti olùdarí ti ilé epo Heyden àti olùdásílẹ̀ First Power Limited. Ní ọjọ́ kewa oṣù kẹta ọdún 2019, ìgbìnmọ̀ ti o n darí ìdìbò ni ilẹ̀ Nàìjíríà èyí tí ó jẹ́ Independent Electoral Commission kede Dapo Abiodun gẹ́gẹ́ bí Gómìnà ti a dìbò yàn ní Ìpínlẹ̀ Ògùn. Wọ́n ṣe ìbúra fún un gẹ́gẹ́ bi Gomina Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ọjọ́ kọnkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún, ọdún 2019 (29 may 2019) Ìgbà ÈweDapọ Abiọdun wa láti Ìpèrù Remọ ni Ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó wá láti ìdílé Ọba. A bi sínú ẹbí dọ́kítà Emmanuel àti Arábìnrin Victoria Abiodun tí wọ́n wá láti Ìpèrù Remọ ní ìla-òrùn Ìpínlẹ̀ Ògùn ni ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karun ọdún 1960 (29 May 1960). ẹ̀kọ́Dapọ Abiọdun kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásìtì Obafẹ́mi Awólọ̀wọ̀ tí ó wà ní Iṣẹ́Dapọ Abiọdun ni alakoso àti olùdarí ilé iṣẹ́ Heyden Petroleum Limited (UPL), ilé iṣẹ́ ti epo ati gaasi ni ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó tún jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ First Power Limited. ÒṣèlúDapọ Abiọdun jẹ́ ọ̀kan lara ọmọ ẹgbẹ́ tí Ó dá ẹgbẹ́ Alábùradà (Peoples Democratic Party) sílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, bíòtilẹ̀jẹ́pé Ó jẹ́ ọ̀kan lara ọmọ ẹgbẹ́ onigbalẹ (All Progressive Congress) lọ́wọ́lọ́wọ́ bayi nígbàtí O fi ẹgbẹ́ ti Ó wà tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ lẹhin ìdìbò gbogboogbo ti ọdún 2015. Ó díje du ipò láti lọ si ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà lati lọ ṣojú ilà oorun ti Ìpínlẹ̀ Ògùn lábẹ́ ẹgbẹ́ onigbale (All Progressive Congress) nínú ìdìbò gbogboogbo tí ó waye ni Nàìjíríà ni ọdún 2015 èyí tí Ó pàdánù rẹ fún ọmọ ẹgbẹ́ Alábùradà (Peoples Democratic Party). Wọ́n yan Dapọ Abiọdun gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan lára àwọn aṣòfin àgbà tí ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 1988 lábẹ́ ẹgbẹ́ United Nigeria Congress Party (UNCP) èyí tí o ti kógbá sí ilé. Ó ti ṣiṣẹ́ sìn lábẹ́ ìgbìmọ̀ aarẹ àti ilé iṣẹ́ lórísirísi.[3] Ní ọdún 2019, Ó díje nínú ìdìbò ti Gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Ògùn labẹ ẹgbẹ́ onigbale (All Progressive Congress). Ó sì borí ìbò na.[4] Ó jẹ́ ọmọ lẹ́hìn kristi tooto ti O si njọsin pẹ̀lú ilé ìjọsìn (Mountain Of Fire And Miracles Ministry). Ó ti jẹri pe pẹ̀lú gbogbo bí àtakò láti má lè dé ófìsì ti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn ṣe pọ̀ tó, Olórun sì tún mú Ò un dé ibẹ̀. Ìgbésí Ayé Ara Rẹ̀Abiodun ṣe ìgbéyàwó sí Bamidele Abiodun lọ́dún 1990, ó sì bí ọmọ márùn-ún, lára rẹ̀ ni olóògbé Olugbenga Abiodun, DJ Nàìjíríà kan tí a tún mọ̀ sí DJ Olu.[5][6] Àwọn ìtọ́kasí
Information related to Dapo Abiodun |
Portal di Ensiklopedia Dunia